﻿Òwe.
21.
Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa; a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi. 
Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀, ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn. 
Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ. 
Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni! 
Ètè àwọn olóye jásí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá. 
Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú. 
Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ, nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́. 
Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́. 
Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà. 
Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 
Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n, nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀. 
Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun. 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́. 
Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò: àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle. 
Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́: ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 
Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye, yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú. 
Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀. 
Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin. 
Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ. 
Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n; ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́. 
Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá. 
Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára, ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú. 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu. 
Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀. 
Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé; nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe. 
Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́: ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró. 
Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni: mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi? 
Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró. 
Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le: ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́. 
Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa. 
A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun: ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa. 
