﻿Saamu.
150.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀, ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀. 
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀. 
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín. 
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín, 
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè, ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro. 
Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
