﻿Saamu.
136.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; 
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: 
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, 
Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; 
Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; 
Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; 
Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; 
Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; 
Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; 
Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; 
Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; 
Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; 
Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; 
Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ 
Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; 
Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já 
Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; 
Ó sì pa àwọn ọba olókìkí 
Sihoni, ọba àwọn ará Amori 
Àti Ogu, ọba Baṣani; 
Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, 
Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, 
Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; 
Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; 
Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo 
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; 
