﻿Saamu.
133.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀. 
Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí, tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni: tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀. 
Bí ìrì Hermoni tí o sàn sórí òkè Sioni. Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láéláé. 
