﻿Saamu.
120.
Orin fún ìgòkè. Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn. 
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn. 
Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn? 
Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀. 
Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari! 
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà. 
Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn. 
