﻿Saamu.
114.
Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè 
Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba. 
Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn. 
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn. 
Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn? 
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn? 
Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu 
tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi. 
