﻿Saamu.
107.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. 
Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá, 
àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, láti àríwá àti Òkun wá. 
Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé. 
Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn. 
Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn 
Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú tí wọn lè máa gbé. 
Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn, 
nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa. 
Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin, 
nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo, 
Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. 
Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn 
Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já. 
Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn. 
Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì. 
Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 
Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú. 
Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn. 
Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú. 
Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. 
Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́ kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀. 
Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá. 
Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú. 
Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè. 
Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi. 
Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin. 
Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn. 
Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́. 
Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ. 
Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. 
Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà. 
Ó sọ odò di aginjù, àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ. 
Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. 
O sọ aginjù di adágún omi àti ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi, 
níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà, wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé. 
Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò máa so èso tí ó dára; 
Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù. 
Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù, 
ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí. 
Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran. 
Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́. 
Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa. 
