﻿Saamu.
105.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀, jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. 
Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i; sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo. 
Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀, jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀. 
Wá Olúwa àti ipá rẹ̀; wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. 
Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ, 
ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. 
Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa: ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé. 
Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, 
májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki. 
Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ, sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé: 
“Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.” 
Nígbà tí wọn kéré níye, wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀ 
wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan sí èkejì. 
Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tiwọn: 
“Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi; má sì ṣe wòlíì mi níbi.” 
Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run; 
Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú. 
Wọn fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀ a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin, 
títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre. 
Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀ àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀ 
Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀, aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní, 
gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n. 
Israẹli wá sí Ejibiti; Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu. 
Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i ó sì mú wọn lágbára jù àwọn ọ̀tá wọn lọ 
Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 
Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, àti Aaroni tí ó ti yàn. 
Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu. 
Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. 
Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó pa ẹja wọn. 
Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá, èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn. 
Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde, ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn 
Ó sọ òjò di yìnyín, àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn; 
Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn. 
Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé, àti kòkòrò ní àìníye, 
wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn, wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run. 
Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn, ààyò gbogbo ipá wọn. 
Ó mú Israẹli jáde ti òun ti fàdákà àti wúrà, nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan. 
Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ, nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n. 
Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí, àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́. 
Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá, ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn. 
Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde; gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ. 
Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀ àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀. 
Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀ 
Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà, wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà, 
kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. 
