﻿Saamu.
93.
Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí. 
Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé. 
A ti gbé òkun sókè, Olúwa, òkun ti gbé ohùn wọn sókè; òkun ti gbé rírú omi wọn sókè. 
Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo. 
Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa. 
