﻿Saamu.
9.
Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi. Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo. 
Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ; èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. 
Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà; wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ. 
Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú; ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo. 
Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run; Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé. 
Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá, ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé. 
Olúwa jẹ ọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́. 
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo. 
Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú. 
Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀. 
Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni; kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe. 
Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú. 
Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú, 
kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ. 
Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́. 
A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀; àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn. 
Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run. 
Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé. 
Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí; jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ. 
Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa; jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela. 
